Wedding nights: Kí ni aṣọ ìbálé túmọ̀ si lálẹ́ ọjọ́ ìgbeyàwó ?

A group of relatives plant a flag of a bloodstained bedsheet
Àkọlé àwòrán Ọ̀nà tí àṣà ìbálé lálẹ́ ìgbeyàwó ń gbà dọdẹ àwọn obìnrin òde òní

Alẹ ọjọ igbeyawo jẹ alẹ ọjọ manigbagbe fun tọkọ taya nitori awọn ohun aramọnda to seese ko waye lalẹ ọjọ naa.

Laye atijọ, alẹ ọjọ igbeyawo jẹ ọjọ ti ọmọbinrin maa n fi sọkan, ti yoo si maa fi oju sọna fun pẹlu awọn obi ati ẹbi rẹ lapapọ.

Eyi ri bẹẹ nitori alẹ yii gan an ni yoo sọ boya ọmọbinrin naa gba ẹkọ, o fi ara balẹ, to si ṣee gbẹmi le abi boya oninabi, akọọgba ọmọ ni.

Iwadii BBC fihan pe, kaakiri agbaye ni wọn ti n ko adiẹ alẹ nipa oorun akọkọ laarin lọkọlaya lalẹ ọjọ igbeyawo.

Ohun to rọ mọ aṣa yii lo kan yatọ diẹ sira wọn

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Asa ka maa fi asọ ori ibusun han lalẹ ni aarọ ọjọ keji igbeyawo wọpọ lawọn agbegbe kan lagbaye, paapa ni Caucasus, ẹjẹ to ba si wa lara asọ ori ibusun naa lo n fi ẹri mulẹ pe ọkọ ba iyawo rẹ nile.

Awọn ẹbi mejeeji yoo maa ki ara wọn ku oriire pe ọja to dara ni awọn ra, ọkọ pe ni ọmọkunrin, iyawo naa si pe ni obinrin, kii se korofo isana, igba yii si ni ayẹyẹ igbeyawo to wa sopin.

Ọpọ isẹlẹ adiitu lo maa n waye lalẹ ọjọ igbeyawo, , ti ko ba si ẹjẹ lori asọ ibusun lalẹ ọjọ igbeyawo, iyawo naa ru igi oyin, to si seese ki wọn le pada sọdọ awọn obi rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

Iru obinrin bẹẹ si ni yoo nira fun lati ri ọkọ miran ti yoo fẹ, tawọn obi ati ẹbi rẹ yoo si maa fi se ẹsin ati ẹlẹya to ba pada sile wọn.

Ni awọn agbegbe miran, awọn ẹbi yoo joko lalẹ ọjọ igbeyawo lẹba yara ti tọkọtaya wa, aibaamọ, iyawo lee fẹ wa ba wọn lati beere fun itọnisọna lori bi yoo ti se pẹlu ọkọ rẹ lori ibusun.

Lẹyin oorun akọkọ lalẹ ọjọ igbeywao, ọkọ yoo na eso Apple pupa sita tabi asọ inuju funfun, ti ẹjẹ wa lara rẹ lati fihan awọn ẹbi pe oun ba iyawo oun nile.

Iriri obinrin kan, Elmira ree lalẹ ọjọ igbeyawo rẹ:

"Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni mi nigba ti mo pari ẹkọ fasiti, awọn obi mi lo wa ọkọ fun mi, ẹni to jẹ aladugbo wa.

Awọn obi mi fẹ ki n se igbeyawo ni kiakia tori ọjọ n lọ bi o tilẹ jẹ pe n ko nifẹ ọkọ ti wọn wa fun mi.

A yatọ sira wa patapata nitori ko kawe rara sugbọn mo fẹ mu inu mama mi dun, ọpọ ẹbi mi si lo ro pe wọn ti ja ibale mi nileewe.

Ni alẹ ọjọ igbeyawo wa, ẹru n ba mi nigba ti mo ri ọkọ mi to n bọ ara silẹ, kia si lo gun ori mi, to n se nkan to fẹ se lai fẹ mọ boya o dun mọ mi ninu.

Lojiji ni ilẹkun si mọ wa lori, ti mo si ri mama mi, iya ọkọ mi, ibatan baba mi meji, ati ẹbi ọkọ mi kan, wọn fẹ mọ boya ọkọ mi ba mi nile, to si ja ibale mi.

Fun iyalẹnu gbogbo wọn, wọn ri asọ ibusun wa to kun fun ibale mi."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionChild Labour: Fífi ọmọ ṣòwò wọ́pọ̀ ní Naijiria