El-Zakzaky: Aago méjìlá ọ̀sán ku ogún ìṣẹ́jú lọ́jọ́ Ẹtì ni bàálù rẹ̀ gúnlẹ̀

Papakọ ofurufu Abuja

Asaaju ikọ ẹlẹsin Shiite, Ibrahim El Zakzaky ati aya rẹ ti gunlẹ si orilẹede Naijiria bayii.

Gẹgẹ bi akọroyin BBC to wa ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe nilu Abuja ti wi, deede aago mejila ku ogun isẹju lọsan ọjọ Ẹti ni baalu Ethiopia E9-11 to gbe tọkọ-taya naa balẹ.

Iroyin naa ni awọn agbofinro ko jẹ ki ẹnikẹni tabi akọroyin kankan fi oju kan Zakzaky ati aya rẹ, titi ti wọn fi gbe wọn gba ọna miran lọ fi si ahamọ.

Ọ̀pọ̀ agbófinró gbàródan sí pápákọ̀ òfurufú Abuja fún ìpadàbọ̀ Zakzaky

Papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe nilu Abuja ti kun fọfọ bayii fun awọn agbofinro ti oju wọn ko rẹrin, ti wọn gbarodan sibẹ fun igbaradi ipadabọ asaaju ẹsin Shiite, Sheik Ibrahim El-Zakzaky lati orilẹede India.

Bẹẹ ba gbagbe, iroyin ti gbalẹ kan pe Zakzaky ti pinnu lati pada si orilẹede Naijiria, lẹyin ti igbesẹ lati mu ko gba itọju nile iwosan Mandata lorilẹede India fori sanpọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akọroyin BBC to wa ni papakọ ofurufu naa salaye pe, aago mejila ọsan yii lo seese ki baalu Ethiopia to gbe Zakzaky balẹ si papakọ ofurufu naa, ti igbaradi si ti doju ọgbagade lati ọdọ awọn agbofinro fun abọ asaaju ẹsin Shiite naa ati aya rẹ.

Iroyin naa ni lara awọn ikọ agbofinro to wa nikalẹ la ti ri awọn ọlọpaa, osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, awọn ologun, ati osisẹ aabo ara ẹni laabo ilu ( Civil Defence).

Image copyright others

Akọroyin BBC ni, gbogbo igbiyanju oun lati ya awọn agbofinro to pọ bii esú naa lo ja si pabo, nitori wọn ko gba akọroyin kankan laaye lati duro sẹba ibi ti wọn wa.

El-Zakzaky fi India sílẹ̀, níbo ni yóò dé sí ní Nàìjíríà?

Image copyright @zakzakysupport

Kii ṣe iroyin mọ pe ede aiyede bẹ silẹ laarin ikọ aṣaaju ẹsin Shiite lorilẹede Naijiria, Ibrahim Elzakzaky ati ijọba India, eyi to n pagidina itọju rẹ lẹyin ti ileejọ fun laaye lọsẹ to kọja.

Ba a ṣe n sọrọ yii, iroyin kan ti ni Ibrahim El-Zakzaky ti n ṣẹri bọ wa sile.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agogo marun irọlẹ ọjọbọ ni iroyin naa gbe pe yoo gbera kuro ni orilẹede India.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi awọn iroyin abẹle ṣe sọ, pẹlu fidio kan ti El-Zakzaky funra rẹ gan ti sọrọ, anfani meji ni wọn fun olori ẹsin naa.

Wọn ni yala ko fara mọ awọn ilana ti ijọba fun un tabi ki wọn daa pada sorilẹede Naijiria, amọ o dabi ẹni pe anfani keji ni El-Zakzaky nawọ mu.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn ọmọlẹyin rẹ n lọọgun pe ohun to n sẹ́lẹ yii ni ọwọ ijọba Naijiria ninu amọ ijọba paapaa n pariwo.

Ijọba ni aifi ọwọ sibi ti ọwọ ngbe aṣaaju ijọ Shitte ọhun lo n faa, ti gbogbo nnkan nipa itọju rẹ nilẹ okeere ṣe lọju pọ.

Nibayii, ibeere to gba ẹnu ọpọ eeyan ni pe, bi ọrọ ṣe wa ri yii, bi El-Zakzaky ba pada de nibo ni yoo wa?

Ṣe ile rẹ ni yoo gba lọ ni, ṣe ileewosan kan ni Naijiria ni yoo lọ ni tabi yoo pada sinu ahamọ awọn agbofinro DSS, eyi to ti wa fun bii ọdun mẹrin gbako?