South West Security: Ọlọ́pàá Ogun àti Ọ̀ṣun ni àwọn kò lọ́wọ́ nínú àjọṣepọ̀ ọ̀hún

Ipade awọn ọga ọlọpaa lorilẹede NAijiria Image copyright @PoliceNG
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ Ọlọpaa ni eto abo agbegbe lawọn n tẹle; OPC ni ọrọ naa ko ti fẹnu jona sibikan

Ọrọ eto aabo to n mẹhẹ ni agbegbe iwọ oorun guusu Naijiria nibi ti ẹya Yoruba ṣodo si, ti di irawọ ọsan to n ba awọn agba lẹru bayii.

Nitorinaa, ni Ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti se kede pe, ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣe aṣepọ pẹlu awọn ẹgbẹ ibilẹ to nii ṣe pẹlu ọrọ aabo ni ilẹ Yoruba bii OPC atawọn ẹgbẹ ọdẹ ibilẹ gbogbo.

Bẹẹ si ni ọpọ ọmọ kootu oojiire nile ati loke okun to gbọ iroyin naa, lo n se yaginni yodo pe ọ̀rọ̀ eto aabo to mẹhẹ ọhun ko ni pẹ lojutu.

Amọ beere to wa gba ọkan awọn eeyan ni pe se gbogbo awọn ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ mẹfẹẹfa to wa lẹkun yii ni eto agbajọ ọwọ naa kan tabi boya ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti nikan lo n da ọwọ wu lori rẹ.

Nigba to n dahun ibeere yii, ọga ọlọpaa nipinlẹ Ekiti sọ fun BBC Yoruba pe, ni ilakaka gbogbo ti ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe nibẹ, lo mu ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọdẹ atawọn ẹgbẹ OPC lati se ọbẹ aabo jinna ni gbogbo agbegbe to wa nilẹ Yoruba.

Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Asuquo Amba wa ṣe apẹrẹ iṣẹlẹ iwadii kan eleyii ti o waye ni inu igbo to wa laala ipinlẹ Ekiti ati Kogi.

O ni awọn ṣe amulo ọgbọn inu ati bi awọn ọdẹ ati ẹgbẹ bii OPC ṣe mọ ọna gbogbo ninu aginju ọhun, lati fi ṣe awari awọn amokunṣika ti wọn fara sinko sinu igbo naa.

Image copyright @PoliceNG

Amọṣa ninu ọrọ tirẹ, ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, Abiọdun Ige pẹlu Akẹgbẹrẹ nipinlẹ Ọyọ, Sina Olukolu ni, awọn ko ni ajọṣepọ kankan pẹlu awọn ẹgbẹ alaabo kankan, eyi to kọja irufẹ ajọṣepọ to wa laarin ọlọpaa atawọn araalu lọ.

Awọn mejeeji ni ohun ti awọn mọ ni pe, bi ẹnikẹni ba ni iroyin to lee ṣe ọlọpaa lanfani lati lee dẹkun iwa ọdaran lawujọ, onitọhun lee mu tọ ọlọpaa wa.

Wọn ni awọn ko tii le sọ pe ajọṣepọ kankan n bẹ laarin awọn ẹgbẹ alaabo yii, ju eyi to wa laarin ọlọpaa ati araalu lọ.

Amọṣa, awọn ọga ọlọpaa ni ipinlẹ mẹtẹẹta naa ni wọn fi ohun kan sọrọ pe, isẹ ọlọpaa lẹsẹkuku jẹ eyi to jẹ ileeṣẹ ọlọpaa logun pupọ bayii.

Image copyright @PoliceNG

Wọn fikun pe eyi kun ara ọna ti wọn fẹ gba lati dẹkun gulegule awọn to n da omi alaafia ilu laamu lẹkun yii.

Ileeṣẹ BBC news Yoruba tun tẹ siwaju lati kan si ẹgbẹ OPC lati mọ boya wọn mọ si igbesẹ ajọsepọ yii ati ipa ti wọn n ko ninu rẹ.

Ọgbẹni Shina Akinpẹlu, to jẹ alukoro fun igun new Era ninu ẹgbẹ OPC ṣalaye fun BBC news Yoruba pe, lootọ ni OPC n gbe igbesẹ labẹnu lati ṣe ajọṣepọ pẹlu awọn agbofinro.

Akinpẹlu ni ọrọ ajọṣepọ naa ko mọ lori ọlọpaa nikan, gbogbo awọn ẹka iṣẹ alaabo ni yoo kopa ninu igbesẹ naa gẹgẹ bi awọn agba majẹobajẹ kan ni ilẹ Yoruba ti ṣe n peelo rẹ.