NURTW: Yasin ní àbẹ̀wò òun sí Makinde dá lórí ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò tó fòfin dè

Seyi Makinde Image copyright Seyi Makinde

Ààrẹ àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NURTW), Alhaji Nojeem Yasin tí fí ọkàn àwọn awakọ ìpínlẹ̀ Ọyọ́ balẹ̀.

O ni pé gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ onímọ-ẹ̀rọ Seyi Makinde yóò yí ìpínnu rẹ̀ padà lóri gbígbẹsẹlé ẹgbẹ́ náà.

Yasin sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tó ń ba àwọn akọròyìn sọ́rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú gómìnà ní ilé ìjọba ni agodi Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ààrẹ àwọn awakọ̀ òhun tó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú àwọn olóyè ẹgbẹ́, sàlàyé pé, gómìnà Makinde ti fí ọkàn àwọn balẹ̀ pé òun ti ṣetan láti kásẹ̀ òfin náà nilẹ̀, ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ̀ ìpínlẹ̀ Ọyọ bá ti ṣetan láti tọpasẹ̀ aláfíà.

Yasin ni " Èrèdí ìrìnàjo mi si ìpínlẹ̀ Ọyọ ni láti rí Gomina Makinde lóri ọ̀rọ̀ àwọn ẹgbẹ́ awakọ, sùgbọ́n gomìnà ni òun fofin de ẹgbẹ awakọ, nítori àláfíà àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ọyọ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

O ni ètò ààbo mẹ́hẹ lasiko naa, ni òun ṣe dá ìgbàkegbodo wọn dúro."