Eèwọ̀ ni láti pa ẹja nínú odò Sogidi ni Aáwẹ́ nipinlẹ Oyo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Sogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

A kìí fun awọn ẹja naa ni ounjẹ kankan -Ojedele

Ilu Aáwẹ́ ni ìpínlẹ̀ Oyo ni guusu Naijiria ni BBC Yoruba lọ lọsẹ yii.

Odo Adagun Sogidi ni BBC lọ ṣe iwadii rẹ nitori ti ọmọ ko ba ba itan, o gbọdọ ba arọba to jẹ baba itan.

Alagba Ọjẹdele Adebayọ to jẹ alamojuto adagun odo Sogidi ni Aawẹ pa itan bi odo yii ṣe jẹ.

O sọrọ kikun lori awọn eewọ odo naa ati abami ẹja ko ṣẹja-ko ṣeeyan to finu adagun odo naa ṣe ibugbe.

Alagba Ojẹdele ṣalaye bi gbogbo ọrọ ti ri lati ọdun 1750 ti wọn ti wa lati Ile Ifẹ to jẹ orisun Yoruba.

Bakan naa lo mẹnuba iriri lori awọn to ti dẹ́jàá sẹyin nipa pipa ẹja inu odo yii ṣeyin.

Ni ipari, igbagbọ la fi n rire gba lọwọ Olorun.

Alagba Ojedele sọrọ lori bi adura awọn eeyan ṣe n gba ti wọn ba tọrọ nkan ninu odo yii.