Oyo Police: Àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́wọ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Ẹyẹ ni àwọn

Awọn osisẹ ọlọpa Image copyright @PoliceNG

Ọwọ palaba awọn akẹkọ mẹẹdogun nile ẹkọ fasiti imọ ẹrọ Ladoke Akintọla, LAUTECH, nilu Ogbomọsọ ti segi lori ẹsun pe wọn digun jale, sise ẹgbẹ okunkun ati iwa agbodegba fun ọdaran.

Kọmisọna ọlọpa fun ipinlẹ Ọyọ, Sina Olukọlu lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n bawọn akọroyin sepade ni olu ileesẹ ọlọpa to wa ni Ẹlẹyẹle nilu Ibadan.

Olukọlu ni awọn osisẹ ọlọpa to n gbogun ti iwa idigunjale, SARS, ni wọn ta mọra, ni kete ti iroyin iwa ọdaran awọn afurasi ọhun de etigbọ wọn, ti wọn si gba wọn mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe orukọ awọn afurasi ọdaran naa ti wa ni akssilẹ awọn lati ọjọ pipẹ fun oniruuru ẹsun iwa ọdaran, tọwọ sinkun awọn osisẹ SARS naa si tẹ wọn lọjọ Kẹfa osu Kẹfa ladugbo Arojẹ, nilu Ogbomosọ ni deede aago meje abọ alẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Olukọlu fikun pe awọn akẹkọ naa ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ni awọn, tawọn si ti n foju awọn eeyan akẹkọ ẹlẹgbẹ awọn ati araalu danrin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionafin pupa

O wa fọwọ idaniloju sọya pe ileesọ ọlọpa ipinlẹ Ọyọ ti setan lati ri pe adinku nla ba iwa ọdaran nipinlẹ yii.

Lara awọn eeyan to ti fori sọta iwa ọdaran lati awọn afurasi ọhun ni arabinrin kan ọga rẹ ran nisẹ, ti wọn si fi oogun gba miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin naira (N1.4M) lọwọ rẹ lasiko to n lọ sile ifowopamọ ladugbo Dugbẹ.