June 12: Buhari yóò la ọ̀na 2,000 kìlómítà, èèyàn 100 yóò yọ nínú òṣì

Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Mo fe gbajumo oro eto aabo lasiko yii

Lasiko ayajọ June 12, ti i se ayajọ ijọba Tiwantiwa, aarẹ Muhammadu Buhari fi akoko naa sọ ọrọ apilkọ rẹ fun saa keji eyi to kun fun ọpọ ileri itunu fawọn ọmọ orilẹede yii.

Bẹẹ ba gbagbe, Aarẹ Buhari bẹrẹ saa keji iṣejọba rẹ ni ọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2019, amọ ti ko ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lẹyin ti wọn bura fun un tan.

Image copyright @Buhari
Àkọlé àwòrán Kókó ọ̀rọ̀ tí Buhari sọ ní àyájọ́ June 12

Gbagede Eagle Square nibi ti Naijiria ti n sami ayẹyẹ iṣejọba Awa ara wa ni Abuja, ni aarẹ Buhari ti wa ba awọn ọmọ Naijira sọrọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ rẹ fun ayajọ June 12, Buhari ṣeleri lati tubọ ri si eto aabo fun ẹ̀mí àti dukia.

Aarẹ Buhari ni, oun gba pe ajọṣepọ wa laarin ìṣẹ́, eto ọrọ ajé ti ko daa pẹlu iwa jẹgudujẹra, lai yọ eto aabo ti ko fini lọkan balẹ silẹ.

Aarẹ Buhari tun ni, ko si nkan to le di Naijiria lọwọ idagbasoke gẹgẹ bii ti China, India ati Indonesia.

Kókó inu ọrọ Aarẹ Buhari:

Aarẹ Buhari bẹrẹ nipa ṣiṣe alaye kikun lori pataki Naijiria ninu idagbasoke iṣejọba alagbada nilẹ Adulawọ.

O mẹnuba awọn aṣeyọri ijọba rẹ ni saa to kọja (2015 si 2019).

Image copyright @pius
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari kede fifi orukọ MKO Abiola pe papa iṣere Abuja

Aarẹ Buhari ni oun ti jagun Boko Haram de ibi to lapẹrẹ lati 2015.

O ni nitootọ iṣẹ yii pọ lati gbogun ti awọn ajinigbe ati agbesunmọmi, ṣugbọn eyi ti di ankoo fawẹẹli gbogbo agbaye.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan ilẹ okeere wa ba Buhari yọ ayọ ayajọ iṣejọba alagbada

O ni ijọba oun ti mojuto ọrọ atunṣe eto ẹkọ ati idagbasoke eto ọrọ aje Naijiria, yatọ si titun awọn opopona ṣe.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Aṣepari awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba rẹ ti bẹrẹ tẹlẹ.

Ileri ti Buhari fẹ gbajumọ ni saa keji iṣejọba rẹ:

Nitootọ Aarẹ Buhari ko soju abẹ niko ni pato lori ileri rẹ, ṣugbọn o ṣapejuwe awọn koko ti ijọba oun yoo gbajumọ lasiko yii bii:

  • Aṣepari awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba rẹ ti bẹrẹ tẹlẹ.
  • Fifopin si ìṣẹ́ àti òṣì ọgọrun un miliọnu eniyan ti wọn ba ni adari rere.
  • Rii wi pe iṣọkan wa laarin eto idajọ Naijiria.
  • Ṣiṣe atunṣe si eto ilera alabọde ati ti ile iwosan ijọba nlanla.
  • Riran awọn olokowo keekeeke lọwọ.
  • Ṣiṣe atilẹyin fun awọn onile iṣẹ nlanla.
Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Buhari gbe ipinnu rẹ fun Naijiria jade loju ọpọ ero ni Eagle Square

Awọn olori orilẹ-ede to wa nijoko nibẹ pẹlu Buhari lasiko ayajọ ijọba tiwa n tiwa naa ni aarẹ orilẹ-ede Rwanda, Chad, Niger ati Gambia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption9th Assembly: Aráàlú ní àwọn ń fẹ́ ìpèsè àwọn ohun èèlò amáyédẹrùn