Saheed Oṣupa: Ọlọ́pọlọ pípé kò leè ṣe òṣèlú Nàìjíríà

Saheed

Gbajugbaja olorin fuji lorilẹede Naijiria, Saheed Osupa ti sọ fun gbogbo awọn ololufẹ rẹ wi pe oun ko ni iyawo ni ile, amọ oun ni ọpọlọpọ ọmọ to jẹ ti ti oun.

Saheed Osupa fi eyi lede lasiko to n ba BBC Yoruba fọrọjomitoro ọrọ lori oju opo ikansiraẹni Facebook ti BBC News Yoruba.

Osupa ni o ni idi ti oun ko fi ni iyawo si ile, amọ o parọwa si awọn ololufẹ rẹ lati fọkan balẹ.

Bakan naa ni olorin gbajugbaja naa sọ wi pe ọlọ́pọlọ pípé kò leè ṣe òṣèlú lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, nitori iwa ẹgbin bii jẹgudujẹra ti o wọpọ ninu oselu orilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌṣẹ̀lẹ̀ jákèjádò orílẹ̀èdè àgbáyé láàárin ìṣẹ́jú kan

Saheed Osupa ni oun ko ni lọkan lati se oselu bayii nitori oun jẹ olooto eniyan ti awọn eniyan fọkan tan.