BB Naija: Ìjọba Ekiti ní Khafi kò tíì ṣẹ̀ sófin débi pé yóò nílò àtìlẹyìn wọn

Kafayat kareem Image copyright AcupofKhafi
Àkọlé àwòrán BBNaija 2019: Kíní ǹkan tí Khafi ó pàdánu tí iṣẹ́ ba bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀

Kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ Ekiti, Gboyega Olumilua ti kede pe Khafi Kareem, to n kopa lori eto BB Naija, to si jẹ ọmọ bibi ipinlẹ naa, ko tii se ohun to lodi sofin debi pe yoo nilo atilẹyin abi idasi ijọba ipinlẹ naa.

Olumilua, lasiko to n dahun ibeere BBC Yoruba ni lootọ ni inu ijọba ipinlẹ naa dun lakọkọ pe awọn ni asoju ni BB naija, to si jẹ oriire fun awọn, sugbọn eto ori itakun agbaye naa ko fi bẹẹ kan ijọba ipinlẹ Ekiti gbọngbọn.

Kọmisana feto iroyin ni Ekiti, nigba taa bi pe se ijọba ipinlẹ Ekiti yoo sugba ọmọ bibi ipinlẹ naa to jẹ ọlọpaa nilẹ Gẹẹsi, to seese ko padanu isẹ rẹ nilẹ Gẹẹsi, Olomilua ni Khafi ko fi igbesẹ rẹ naa to ijọba ipinlẹ Ekiti leti lasiko ti eto BB Naija fẹ bẹrẹ.

Image copyright AcupofKhafi
Àkọlé àwòrán Kíní ǹkan tí Kafayat Kareem ó pàdánu tí iṣẹ́ ba bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀

O ni bi Khafi se ni ibalopọ pẹlu akẹẹgbẹ rẹ lori eto BB Naija tako asa ati ise ọmọ Yoruba to maa n bọwọ fun ara wọn, ti asa ilẹ Kaarọ oojire si lodi si iru iwa bayi lojutaye.

Olumilua wa ni taa ba tun wo ohun ti Khafi se, iru asa yii wọpọ lori eto BB Naija latẹyin wa, ko si tii se ohun to lodi sofin, tabi sẹ ẹsẹ to lowura debi pe wọn yoo ran ni ẹwọn tabi gbẹmi rẹ, eyi to nilo ki ijọba ipinlẹ rẹ tete da si.

Kí ní Khafi BB Naija yóò pàdánu tí iṣẹ́ ba bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti ń sọ èrò ọkàn wọ́n lóri awuyewuye tó bẹ́ sílẹ̀ lóri Khapilat Kareem ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Khafi, tó ń kopa nínú eré àgbéléwò BBNaija tó ń lọ lọ́wọ́.

Wọ́n fi ẹ̀sùn kan akópa náà wí pe, ó huwà àìtọ tí kò si bá ìlànà iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bii ọlọ́pàá ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí (MET Police) mu.

Ilé iṣẹ́ ọlọpàá náà si ti gbé àtẹ̀jáde kan síta pé, ìwà ti òṣìṣẹ́ wọ́n yìí hù kò bá ìlànà òfin tó dé iṣẹ́ náà mu, nítori ìdí èyí, àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, ó sì ṣeeṣe kí Khapilat Kareem pàdánù iṣẹ́ rẹ̀.

ní ǹkan ti Khafi le pàdánù:

Gẹ́gẹ́ bí ọlọpàá MET ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì wà ni ipò ti Khapilat Kareem wa lẹ́nú iṣẹ́, ó ni ẹ̀tọ́ sí owó osù bíí ẹgbẹ̀rún mọ́kàndílógójì poun (£39,000) lọ́dun.

Èyí tó túmọ sí míliọ̀nù kàn ààbọ Náìrà lósù ( ₦1.5m), tó bá ti ṣiṣẹ́ láàrin ọdún mẹ́rìn sí méje, to si wa ni ipò tí Khapilat wa gẹ́gẹ́ bii kọ́bùrù ọlọ́pàá, Police Constable (PC).

Owó Ọdún kan Owó Oṣù kan

£23, 124 sí £38,382 £1,927 sí £3,198.5

#11,099,520 sí #18,423,360 #924,960 sí #1,535,280

Ẹ̀wẹ̀, Àwọn to ń ṣe àmójúto ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ Khafi sàlàyè pé, Kafayat Kareem kò gbọ́ sí gbogbo ǹkan tó ń lọ lóde, yòó si fèsì sí gbogbo ẹ̀sùn yìí nígbà to ba jáde.

Bákàn náà ni, wọ́n ní àwọn ń fẹ́ ki ìwé ìròyìn SUN UK tọrọ àforíjí nítori pe wọ́n kò gbọ́ ìhà ti Khafi, ki wọ́n tó gbé ìròyìn náà jáde.

Wọ́n tún fi kún pé àwọn yóò pẹjọ lóri ọ̀rọ̀ náà, atẹjade ti wọn fi sita ree nisalẹ:

Image copyright Instagram/acupofkhafi
Àkọlé àwòrán Eto BB Naija

Ọ̀rọ̀ Khafi túbọ̀ n da aríwò sílẹ̀ lórí òpó Twitter lóri bóyánǹkan ti Khafi ṣe dára tàbí kò dára.